John 7:1-10

Jesu lọ sí àjọ ìpàgọ́

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jesu ń rìn ní Galili: nítorí tí kò fẹ́ rìn ní Judea, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa. 2 aÀjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan. 3 bNítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhìn-ín-yìí, kí o sì lọ sí Judea, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fi iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé. 4Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkára rẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.” 5Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbà á gbọ́.

6 cNítorí náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Àkókò gan an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín. 7 dAyé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú. 8Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.” 9Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Galili síbẹ̀.

10Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀.
Copyright information for YorBMYO